33 Kí o fi aṣọ ìdábùú náà kọ́ sábẹ́ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí Ẹ̀rí náà+ wọnú ibi tí aṣọ ìdábùú náà bò. Aṣọ ìdábùú náà ni kí ẹ fi pín Ibi Mímọ́+ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ.+
2 Torí wọ́n kọ́ apá àkọ́kọ́ nínú àgọ́, níbi tí ọ̀pá fìtílà,+ tábìlì àti àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú*+ wà; a sì ń pè é ní Ibi Mímọ́.+3 Àmọ́ lẹ́yìn aṣọ ìdábùú kejì,+ apá kan wà tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ.+