-
Hébérù 9:2-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Torí wọ́n kọ́ apá àkọ́kọ́ nínú àgọ́, níbi tí ọ̀pá fìtílà,+ tábìlì àti àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú*+ wà; a sì ń pè é ní Ibi Mímọ́.+ 3 Àmọ́ lẹ́yìn aṣọ ìdábùú kejì,+ apá kan wà tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ.+ 4 Àwo tùràrí oníwúrà+ àti àpótí májẹ̀mú + tí wọ́n fi wúrà bò látòkè délẹ̀+ wà níbẹ̀, inú rẹ̀ ni ìṣà wúrà tí wọ́n kó mánà+ sí wà pẹ̀lú ọ̀pá Áárónì tó yọ òdòdó+ àti àwọn wàláà+ májẹ̀mú;
-