-
Ẹ́kísódù 39:8-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ó wá mú kí ẹni tó ń kó iṣẹ́ sí aṣọ ṣe aṣọ ìgbàyà,+ bí wọ́n ṣe ṣe éfódì, ó lo wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa.+ 9 Tí wọ́n bá ṣẹ́ ẹ po sí méjì, ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba. Wọ́n ṣe aṣọ ìgbàyà náà, tó jẹ́ pé tí wọ́n bá ṣẹ́ ẹ po sí méjì, gígùn rẹ̀ àti fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.* 10 Wọ́n to òkúta sára rẹ̀ ní ìpele mẹ́rin. Ìpele àkọ́kọ́ jẹ́ rúbì, tópásì àti émírádì. 11 Ìpele kejì jẹ́ tọ́kọ́wásì, sàfáyà àti jásípérì. 12 Ìpele kẹta jẹ́ òkúta léṣémù,* ágétì àti ámétísì. 13 Ìpele kẹrin jẹ́ kírísóláítì, ónísì àti jéèdì. Wọ́n lẹ̀ wọ́n mọ́ ìtẹ́lẹ̀ tí wọ́n fi wúrà ṣe. 14 Àwọn òkúta náà dúró fún orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì méjìlá (12), wọ́n sì fín àwọn orúkọ náà sára òkúta bí èdìdì, orúkọ kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjìlá (12) náà.
-