-
Ẹ́kísódù 39:19-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì fi wọ́n sí igun méjèèjì aṣọ ìgbàyà náà ní inú, ó dojú kọ éfódì náà.+ 20 Wọ́n tún ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì fi wọ́n síwájú éfódì náà, nísàlẹ̀ àwọn aṣọ èjìká méjèèjì éfódì náà, nítòsí ibi tí wọ́n ti so pọ̀, ní òkè ibi tí àmùrè* tí wọ́n hun ti so mọ́ éfódì náà. 21 Níkẹyìn, wọ́n fi okùn aláwọ̀ búlúù so àwọn òrùka aṣọ ìgbàyà náà mọ́ àwọn òrùka éfódì náà, kí aṣọ ìgbàyà náà lè dúró lórí éfódì náà, lókè àmùrè* tí wọ́n hun, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
-