-
Ẹ́kísódù 28:26-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Kí o ṣe òrùka wúrà méjì, kí o sì fi wọ́n sí igun méjèèjì aṣọ ìgbàyà náà ní inú, kó dojú kọ éfódì náà.+ 27 Kí o tún ṣe òrùka wúrà méjì síwájú éfódì náà, nísàlẹ̀ aṣọ èjìká méjèèjì lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tó ti so pọ̀, lókè àmùrè* éfódì náà tí wọ́n hun.+ 28 Kí o fi okùn aláwọ̀ búlúù di aṣọ ìgbàyà náà mú, kí o fi okùn náà so àwọn òrùka aṣọ ìgbàyà náà mọ́ àwọn òrùka éfódì. Èyí máa mú kí aṣọ ìgbàyà náà dúró lórí éfódì náà, lókè àmùrè* éfódì tí wọ́n hun.
-