30 Níkẹyìn, wọ́n fi ògidì wúrà ṣe irin pẹlẹbẹ tó ń dán, tó jẹ́ àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́, wọ́n sì fín ọ̀rọ̀ sára rẹ̀ bí ẹni fín èdìdì, pé: “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà.”+ 31 Wọ́n so okùn tí wọ́n fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ṣe mọ́ ọn, kí wọ́n lè dè é mọ́ láwàní náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.