35 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tí Mósè sọ fún wọn, wọ́n béèrè àwọn ohun èlò fàdákà àti wúrà pẹ̀lú aṣọ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì.+ 36 Jèhófà mú kí àwọn èèyàn náà rí ojú rere àwọn ará Íjíbítì, wọ́n fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè, wọ́n sì gba tọwọ́ àwọn ará Íjíbítì.+