-
Diutarónómì 4:15-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Torí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi,* torí pé ẹ ò rí ẹnikẹ́ni lọ́jọ́ tí Jèhófà bá yín sọ̀rọ̀ ní Hórébù láti àárín iná náà, 16 kí ẹ má bàa hùwàkiwà nípa gbígbẹ́ ère èyíkéyìí tó jọ ohunkóhun fún ara yín, ohun tó rí bí akọ tàbí abo,+ 17 ohun tó rí bí ẹranko èyíkéyìí ní ayé, bí ẹyẹ tó ń fò lójú ọ̀run,+ 18 bí ohunkóhun tó ń rákò lórí ilẹ̀ tàbí tó rí bí ẹja èyíkéyìí nínú omi lábẹ́ ilẹ̀.+
-