ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 33:22, 23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Tí ògo mi bá ń kọjá, màá fi ọ́ pa mọ́ sínú ihò àpáta, màá sì fi ọwọ́ mi bò ọ́ títí màá fi kọjá. 23 Lẹ́yìn náà, màá gbé ọwọ́ mi kúrò, ìwọ yóò sì rí ẹ̀yìn mi. Àmọ́ o ò ní rí ojú mi.”+

  • Nọ́ńbà 12:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ojúkojú* ni mò ń bá a sọ̀rọ̀,+ láì fọ̀rọ̀ pa mọ́, kì í ṣe lówelówe; ìrísí Jèhófà ló sì ń rí. Kí wá nìdí tí ẹ̀rù ò fi bà yín láti sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí Mósè ìránṣẹ́ mi?”

  • Diutarónómì 34:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Àmọ́ látìgbà náà, kò tíì sí wòlíì kankan ní Ísírẹ́lì bíi Mósè,+ ẹni tí Jèhófà mọ̀ lójúkojú.+

  • Jòhánù 1:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Kò sí èèyàn tó rí Ọlọ́run rí;+ ọlọ́run bíbí kan ṣoṣo+ tó wà ní ẹ̀gbẹ́ Baba*+ ni ẹni tó ṣàlàyé Rẹ̀.+

  • Jòhánù 6:46
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 46 Kì í ṣe pé èèyàn kankan ti rí Baba,+ àfi ẹni tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run; ẹni yìí ti rí Baba.+

  • Ìṣe 7:38
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 38 Ẹni yìí wà lára ìjọ tó wà ní aginjù, ó wà pẹ̀lú áńgẹ́lì+ tó bá a sọ̀rọ̀+ lórí Òkè Sínáì pẹ̀lú àwọn baba ńlá wa, ó sì gba àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́ tó jẹ́ ààyè láti fún wa.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́