ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 5:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Kó tún mú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀ wá fún Jèhófà torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá,+ ìyẹn abo ẹran látinú agbo ẹran láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ó lè jẹ́ abo ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí abo ọmọ ewúrẹ́. Àlùfáà yóò wá ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

  • Léfítíkù 6:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Kó sì mú àgbò tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún àlùfáà láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi fún Jèhófà, kí àgbò náà tó iye tí wọ́n dá lé e, láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi.+

  • Léfítíkù 14:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 “Èyí ni òfin tí ẹ ó máa tẹ̀ lé nípa adẹ́tẹ̀, ní ọjọ́ tí àlùfáà máa kéde rẹ̀ pé ó ti di mímọ́, tí wọ́n á sì mú un wá sọ́dọ̀ àlùfáà.+

  • Léfítíkù 14:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Kí àlùfáà mú ọmọ àgbò kan, kó fi rú ẹbọ ẹ̀bi+ pẹ̀lú òróró òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì náà, kó sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà.+

  • Léfítíkù 19:20, 21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 “‘Tí ọkùnrin kan bá dùbúlẹ̀ ti obìnrin kan, tó sì bá a lò pọ̀, tó sì jẹ́ pé ìránṣẹ́ ọkùnrin míì ni obìnrin náà, àmọ́ tí wọn ò tíì rà á pa dà tàbí dá a sílẹ̀, ẹ gbọ́dọ̀ fìyà jẹ wọ́n. Àmọ́, ẹ má pa wọ́n, torí wọn ò tíì dá obìnrin náà sílẹ̀. 21 Kí ọkùnrin náà mú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀ wá fún Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àgbò kan fún ẹbọ ẹ̀bi.+

  • Nọ́ńbà 6:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Kó tún ara rẹ̀ yà sọ́tọ̀ fún Jèhófà ní àwọn ọjọ́ tó fi jẹ́ Násírì, kó sì mú ọmọ àgbò ọlọ́dún kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi. Àmọ́ kò ní ka àwọn ọjọ́ tó ti kọjá torí ó ti ba Násírì rẹ̀ jẹ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́