- 
	                        
            
            Ẹ́kísódù 29:27, 28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        27 Kí o ya igẹ̀ ọrẹ fífì náà sí mímọ́, pẹ̀lú ẹsẹ̀ ìpín mímọ́ tí o fì, èyí tí o gé lára àgbò àfiyanni náà,+ látinú ohun tí o fi rúbọ torí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀. 28 Yóò di ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó jẹ́ àṣẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa pa mọ́ títí láé, torí ìpín mímọ́ ló jẹ́, yóò sì di ìpín mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa fún wọn.+ Ìpín mímọ́ wọn fún Jèhófà ni, látinú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wọn.+ 
 
-