-
Ẹ́kísódù 29:15-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Kí o wá mú ọ̀kan lára àwọn àgbò náà, kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí àgbò náà.+ 16 Kí o pa àgbò náà, kí o mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o sì wọ́n ọn sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà.+ 17 Gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, kí o fọ ìfun rẹ̀+ àti ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì to àwọn ègé ẹran náà pẹ̀lú orí rẹ̀. 18 Kí o sun àgbò náà lódindi, jẹ́ kó rú èéfín lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ló jẹ́ sí Jèhófà, olóòórùn dídùn.*+ Ó jẹ́ ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.
-
-
Léfítíkù 1:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹran náà, ọrẹ rẹ̀ yóò sì ní ìtẹ́wọ́gbà, á sì jẹ́ ètùtù fún un.
-