Léfítíkù 2:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 2 “‘Tí ẹnì* kan bá fẹ́ mú ọrẹ ọkà+ wá fún Jèhófà, kó jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná, kó da òróró sórí rẹ̀, kó sì fi oje igi tùràrí sórí rẹ̀.+ Léfítíkù 2:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 “‘Ẹ má ṣe mú ọrẹ ọkà kankan tó ní ìwúkàrà+ wá fún Jèhófà, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ mú kí àpòrọ́ kíkan tàbí oyin èyíkéyìí rú èéfín bí ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. Léfítíkù 2:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 “‘Kí ẹ fi iyọ̀ dun gbogbo ọrẹ ọkà tí ẹ bá mú wá; ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iyọ̀ májẹ̀mú Ọlọ́run yín di àwátì nínú ọrẹ ọkà yín. Kí ẹ máa fi iyọ̀+ sí gbogbo ọrẹ yín.
2 “‘Tí ẹnì* kan bá fẹ́ mú ọrẹ ọkà+ wá fún Jèhófà, kó jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná, kó da òróró sórí rẹ̀, kó sì fi oje igi tùràrí sórí rẹ̀.+
11 “‘Ẹ má ṣe mú ọrẹ ọkà kankan tó ní ìwúkàrà+ wá fún Jèhófà, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ mú kí àpòrọ́ kíkan tàbí oyin èyíkéyìí rú èéfín bí ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.
13 “‘Kí ẹ fi iyọ̀ dun gbogbo ọrẹ ọkà tí ẹ bá mú wá; ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iyọ̀ májẹ̀mú Ọlọ́run yín di àwátì nínú ọrẹ ọkà yín. Kí ẹ máa fi iyọ̀+ sí gbogbo ọrẹ yín.