-
Diutarónómì 14:12-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ẹyẹ yìí: idì, idì ajẹja, igún dúdú,+ 13 àwòdì pupa, àwòdì dúdú, onírúurú ẹyẹ aṣọdẹ, 14 gbogbo onírúurú ẹyẹ ìwò, 15 ògòǹgò, òwìwí, ẹyẹ àkẹ̀, onírúurú àṣáǹwéwé, 16 òwìwí kékeré, òwìwí elétí gígùn, ògbùgbú, 17 ẹyẹ òfú, igún, ẹyẹ àgò, 18 ẹyẹ àkọ̀, onírúurú ẹyẹ wádòwádò, àgbìgbò àti àdán. 19 Gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́ tó ń gbá yìn-ìn* pẹ̀lú jẹ́ aláìmọ́ fún yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n.
-