-
Léfítíkù 14:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Èyí ni òfin tí ẹ ó máa tẹ̀ lé nípa adẹ́tẹ̀, ní ọjọ́ tí àlùfáà máa kéde rẹ̀ pé ó ti di mímọ́, tí wọ́n á sì mú un wá sọ́dọ̀ àlùfáà.+
-
-
Léfítíkù 14:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “Kí ẹni tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́ fọ aṣọ rẹ̀, kó fá gbogbo irun rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, yóò sì di mímọ́. Lẹ́yìn náà, ó lè wá sínú ibùdó, àmọ́ ìta àgọ́ rẹ̀ ni kó máa gbé fún ọjọ́ méje.
-
-
Léfítíkù 15:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Kí ẹni tó bá fara kan ibùsùn rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+
-
-
Nọ́ńbà 19:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Kí ẹni tó kó eérú màlúù náà jọ fọ aṣọ rẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.
“‘Kí èyí jẹ́ àṣẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àjèjì tí wọ́n jọ ń gbé á máa tẹ̀ lé títí lọ.+
-