24 Ẹ lè fi nǹkan wọ̀nyí sọ ara yín di aláìmọ́. Gbogbo ẹni tó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.+25 Kí ẹnikẹ́ni tó bá gbé òkú èyíkéyìí lára wọn fọ aṣọ rẹ̀;+ onítọ̀hún yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.
46 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá wọnú ilé náà ní èyíkéyìí nínú àwọn ọjọ́ tí wọ́n fi ti ilé náà pa,+ kí ẹni náà jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́;+47 kí ẹnikẹ́ni tó bá dùbúlẹ̀ sínú ilé náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ẹnikẹ́ni tó bá sì jẹun nínú ilé náà fọ aṣọ rẹ̀.
15 Tí ẹnikẹ́ni* bá jẹ òkú ẹran tàbí èyí tí ẹran inú igbó fà ya,+ ì báà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àjèjì ló jẹ ẹ́, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì di aláìmọ́ títí di alẹ́;+ lẹ́yìn náà, á di mímọ́.