-
Léfítíkù 14:49-53Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
49 Kó lè wẹ ẹ̀gbin* kúrò nínú ilé náà, kó mú ẹyẹ méjì, igi kédárì, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti ewéko hísópù.+ 50 Kó pa ẹyẹ kan nínú ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe lórí omi tó ń ṣàn. 51 Kó wá mú igi kédárì náà, ewéko hísópù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti ààyè ẹyẹ náà, kó rì wọ́n bọnú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tó pa, kó sì rì wọ́n bọnú omi tó ń ṣàn náà, kó wá wọ́n ọn sára ilé náà lẹ́ẹ̀méje.+ 52 Kó fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà, omi tó ń ṣàn, ààyè ẹyẹ, igi kédárì, ewéko hísópù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò wẹ ẹ̀gbin* kúrò nínú ilé náà. 53 Kó wá tú ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ ní ẹ̀yìn ìlú náà, lórí pápá gbalasa, kó sì ṣe ètùtù fún ilé náà, ilé náà yóò sì di mímọ́.
-
-
Nọ́ńbà 19:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Kí àlùfáà wá mú igi kédárì, ewéko hísópù+ àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, kó sì jù ú sínú iná tí wọ́n ti ń sun màlúù náà.
-