-
Léfítíkù 15:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 “‘Ibùsùn èyíkéyìí tí ẹni tí ohun kan ń dà jáde lára rẹ̀ bá dùbúlẹ̀ sí yóò di aláìmọ́, ohunkóhun tó bá sì jókòó lé yóò di aláìmọ́. 5 Kí ẹni tó bá fara kan ibùsùn rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 6 Kí ẹnikẹ́ni tó bá jókòó sórí ohun tí ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀ jókòó lé fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.
-