5 “Tí àwọn arákùnrin bá jọ ń gbé, tí ọ̀kan nínú wọn sì kú láìní ọmọ, ìyàwó èyí tó kú kò gbọ́dọ̀ fẹ́ ẹni tí kì í ṣe mọ̀lẹ́bí ọkọ rẹ̀. Kí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ọkọ rẹ̀ lọ bá a, kó sì fi ṣe aya, kó ṣú u lópó.+
17 Torí Hẹ́rọ́dù fúnra rẹ̀ ti ránṣẹ́ pé kí wọ́n lọ mú Jòhánù, ó sì dè é sínú ẹ̀wọ̀n nítorí Hẹrodíà ìyàwó Fílípì arákùnrin rẹ̀, torí ó ti fẹ́ obìnrin náà.+18 Jòhánù sì ti ń sọ fún Hẹ́rọ́dù pé: “Kò bófin mu fún ọ láti fẹ́ ìyàwó arákùnrin rẹ.”+