17 Àmọ́ kó fi iná sun+ ohunkóhun tó bá ṣẹ́ kù di ọjọ́ kẹta lára ẹran tó fi rúbọ. 18 Tí wọ́n bá jẹ èyíkéyìí lára ẹran ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta, ẹni tó mú un wá kò ní rí ìtẹ́wọ́gbà. Kò ní rí ojú rere; ohun tí kò tọ́ ni, ẹni tó bá sì jẹ lára rẹ̀ yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.+