Léfítíkù 25:17 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 17 Ẹnì kankan nínú yín ò gbọ́dọ̀ rẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ,+ ẹ sì gbọ́dọ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run yín,+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.+ Nehemáyà 5:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Àmọ́, àwọn gómìnà tó wà ṣáájú mi ti di ẹrù tó wúwo sórí àwọn èèyàn náà, wọ́n sì ń gba ogójì (40) ṣékélì* fàdákà lọ́wọ́ wọn fún oúnjẹ àti wáìnì lójoojúmọ́. Àwọn ìránṣẹ́ wọn tún ń ni àwọn èèyàn lára. Ṣùgbọ́n mi ò ṣe bẹ́ẹ̀+ nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run.+ Òwe 1:7 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 7 Ìbẹ̀rù* Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀.+ Àwọn òmùgọ̀ ni kì í ka ọgbọ́n àti ìbáwí sí.+ Òwe 8:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìkórìíra ohun búburú.+ Mo kórìíra ìṣefọ́nńté àti ìgbéraga+ àti ọ̀nà ibi àti ọ̀rọ̀ àyídáyidà.+ 1 Pétérù 2:17 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 17 Ẹ máa bọlá fún onírúurú èèyàn,+ ẹ máa nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará,*+ ẹ máa bẹ̀rù Ọlọ́run,+ ẹ bọlá fún ọba.+
17 Ẹnì kankan nínú yín ò gbọ́dọ̀ rẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ,+ ẹ sì gbọ́dọ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run yín,+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.+
15 Àmọ́, àwọn gómìnà tó wà ṣáájú mi ti di ẹrù tó wúwo sórí àwọn èèyàn náà, wọ́n sì ń gba ogójì (40) ṣékélì* fàdákà lọ́wọ́ wọn fún oúnjẹ àti wáìnì lójoojúmọ́. Àwọn ìránṣẹ́ wọn tún ń ni àwọn èèyàn lára. Ṣùgbọ́n mi ò ṣe bẹ́ẹ̀+ nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run.+
13 Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìkórìíra ohun búburú.+ Mo kórìíra ìṣefọ́nńté àti ìgbéraga+ àti ọ̀nà ibi àti ọ̀rọ̀ àyídáyidà.+
17 Ẹ máa bọlá fún onírúurú èèyàn,+ ẹ máa nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará,*+ ẹ máa bẹ̀rù Ọlọ́run,+ ẹ bọlá fún ọba.+