-
Diutarónómì 1:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 “Nígbà yẹn, mo sọ fún àwọn onídàájọ́ yín pé, ‘Tí ẹ bá ń gbọ́ ẹjọ́ láàárín àwọn arákùnrin yín, kí ẹ máa fi òdodo ṣèdájọ́+ láàárín ọkùnrin kan àti arákùnrin rẹ̀ tàbí àjèjì tí ẹ jọ ń gbé.+ 17 Ẹ ò gbọ́dọ̀ gbè sápá kan nínú ìdájọ́.+ Bí ẹ ṣe máa gbọ́ ẹjọ́ ẹni tó kéré ni kí ẹ ṣe gbọ́ ti ẹni ńlá.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn èèyàn dẹ́rù bà yín,+ torí Ọlọ́run ló ni ìdájọ́;+ tí ẹjọ́ kan bá sì le jù fún yín, kí ẹ gbé e wá sọ́dọ̀ mi, màá sì gbọ́ ọ.’+
-
-
2 Kíróníkà 19:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ó sọ fún àwọn onídàájọ́ náà pé: “Ẹ fiyè sí ohun tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí kì í ṣe èèyàn lẹ̀ ń ṣojú fún tí ẹ bá ń dájọ́, Jèhófà ni, ó sì wà pẹ̀lú yín nígbà tí ẹ bá ń ṣe ìdájọ́.+
-
-
Róòmù 2:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Nítorí kò sí ojúsàájú lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+
-