Léfítíkù 21:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Sọ fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Áárónì pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín ò gbọ́dọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ torí ẹni* tó kú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+ Nọ́ńbà 19:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Ẹnikẹ́ni tó bá fara kan òkú èèyàn* máa jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.+ Nọ́ńbà 19:22 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 22 Ohunkóhun tí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ bá fara kàn yóò di aláìmọ́, ẹni* tó bá sì fara kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.’”+
21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Sọ fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Áárónì pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín ò gbọ́dọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ torí ẹni* tó kú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+
22 Ohunkóhun tí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ bá fara kàn yóò di aláìmọ́, ẹni* tó bá sì fara kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.’”+