21Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Sọ fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Áárónì pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín ò gbọ́dọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ torí ẹni* tó kú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+
2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ní kí gbogbo adẹ́tẹ̀+ jáde kúrò nínú ibùdó àti gbogbo ẹni tí nǹkan ń dà lára rẹ̀+ pẹ̀lú gbogbo ẹni tí òkú èèyàn*+ ti sọ di aláìmọ́.
9 Àmọ́ tí ẹnì kan bá dédé kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ tó sì sọ irun rẹ̀ di aláìmọ́, irun tó fi hàn pé ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run,* ó gbọ́dọ̀ fá orí rẹ̀+ ní ọjọ́ tí wọ́n bá kéde pé ó ti di mímọ́. Kó fá a ní ọjọ́ keje.
6 Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọkùnrin kan di aláìmọ́ torí wọ́n fara kan òkú èèyàn,*+ wọn ò wá lè ṣètò ẹbọ Ìrékọjá ní ọjọ́ yẹn. Torí náà, àwọn ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ Mósè àti Áárónì ní ọjọ́ yẹn,+
19 Kí ẹ pàgọ́ sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje. Kí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti pa èèyàn* àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti fara kan ẹni tí wọ́n pa+ wẹ ara yín+ mọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje, ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ kó lẹ́rú.