14 Kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ tún jẹ igẹ̀ ọrẹ fífì àti ẹsẹ̀ ìpín mímọ́+ ní ibi tó mọ́, torí mo ti fi ṣe ìpín rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ látinú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
19 Gbogbo ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú wá fún Jèhófà+ ni mo ti fún ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ pẹ̀lú rẹ, kó jẹ́ ìpín+ yín títí lọ. Ó jẹ́ májẹ̀mú iyọ̀* tó máa wà títí lọ níwájú Jèhófà fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ.”