-
Léfítíkù 25:25-27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 “‘Tí arákùnrin rẹ bá di aláìní, tó sì tà lára ohun ìní rẹ̀, kí olùtúnrà tó bá a tan tímọ́tímọ́ wá ra ohun tí arákùnrin rẹ̀ tà pa dà.+ 26 Tí ẹnì kan ò bá ní olùtúnrà, àmọ́ tó ti wá lọ́rọ̀, tó sì lágbára láti tún ohun ìní náà rà, 27 kó ṣírò iye rẹ̀ láti ọdún tó ti tà á, kó sì dá owó tó ṣẹ́ kù pa dà fún ẹni tó tà á fún. Ohun ìní rẹ̀ á wá pa dà di tirẹ̀.+
-