-
Diutarónómì 11:13-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 “Tí ẹ bá ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́ délẹ̀délẹ̀, èyí tí mò ń pa fún yín lónìí, tí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín, tí ẹ fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín sìn ín,+ 14 màá mú kí òjò rọ̀ sórí ilẹ̀ yín ní àkókò rẹ̀, òjò ìgbà ìkórè àti ti ìgbà ìrúwé, ẹ sì máa kó ọkà yín jọ àti wáìnì tuntun yín àti òróró yín.+ 15 Màá mú kí ewéko hù ní oko yín fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ẹ máa jẹun, ẹ sì máa yó.+
-