Diutarónómì 4:29 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 29 “Tí ẹ bá wá Jèhófà Ọlọ́run yín níbẹ̀, ó dájú pé ẹ máa rí i+ tí ẹ bá fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín wá a.+ Diutarónómì 6:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ+ àti gbogbo okun rẹ*+ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Diutarónómì 10:12 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 12 “Ní báyìí, ìwọ Ísírẹ́lì, kí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ kí o ṣe?+ Kò ju pé: kí o máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ kí o máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí o máa fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ Mátíù 22:37 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 37 Ó sọ fún un pé: “‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà* Ọlọ́run rẹ.’+
29 “Tí ẹ bá wá Jèhófà Ọlọ́run yín níbẹ̀, ó dájú pé ẹ máa rí i+ tí ẹ bá fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín wá a.+
12 “Ní báyìí, ìwọ Ísírẹ́lì, kí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ kí o ṣe?+ Kò ju pé: kí o máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ kí o máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí o máa fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+
37 Ó sọ fún un pé: “‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà* Ọlọ́run rẹ.’+