-
Diutarónómì 28:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Àmọ́ tí o ò bá pa gbogbo àṣẹ àti òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, láti fi hàn pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀, gbogbo ègún yìí máa wá sórí rẹ, ó sì máa bá ọ:+
-
-
1 Sámúẹ́lì 4:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Torí náà, àwọn Filísínì jà, wọ́n ṣẹ́gun Ísírẹ́lì,+ kálukú wọn sì sá lọ sí ilé rẹ̀. Ìpakúpa náà pọ̀; ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000) àwọn ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn ló kú lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
-