Àìsáyà 1:16 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 16 Ẹ wẹ ara yín, ẹ jẹ́ kí ara yín mọ́;+Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi;Ẹ jáwọ́ nínú ìwà burúkú.+ Jeremáyà 2:30 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 30 Lásán ni mo lu àwọn ọmọ yín.+ Wọn kò ní gba ìbáwí;+Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín,+Bíi kìnnìún tó ń wá ẹran kiri. Jeremáyà 5:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Jèhófà, ǹjẹ́ kì í ṣe àwọn olóòótọ́ ni ojú rẹ ń wò?+ O lù wọ́n, ṣùgbọ́n wọn ò mọ̀ ọ́n lára.* O pa wọ́n run, àmọ́ wọn ò gba ìbáwí.+ Wọ́n mú ojú wọn le ju àpáta lọ,+Wọn kò sì yí pa dà.+
30 Lásán ni mo lu àwọn ọmọ yín.+ Wọn kò ní gba ìbáwí;+Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín,+Bíi kìnnìún tó ń wá ẹran kiri.
3 Jèhófà, ǹjẹ́ kì í ṣe àwọn olóòótọ́ ni ojú rẹ ń wò?+ O lù wọ́n, ṣùgbọ́n wọn ò mọ̀ ọ́n lára.* O pa wọ́n run, àmọ́ wọn ò gba ìbáwí.+ Wọ́n mú ojú wọn le ju àpáta lọ,+Wọn kò sì yí pa dà.+