-
Jóṣúà 7:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní lè dìde sí àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n á yí pa dà lẹ́yìn àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n á sì sá lọ, torí wọ́n ti di ohun tí a máa pa run. Mi ò ní wà pẹ̀lú yín mọ́, àfi tí ẹ bá run ohun tí a máa pa run tó wà láàárín yín.+
-
-
Jeremáyà 37:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Kódà bí ẹ bá pa gbogbo ọmọ ogun Kálídíà tó ń bá yín jà, tó sì jẹ́ pé àwọn tó fara pa nìkan ló ṣẹ́ kù, wọ́n ṣì máa wá látinú àgọ́ wọn, wọ́n á sì dáná sun ìlú yìí.”’”+
-