10 Kí ẹ ya ọdún àádọ́ta (50) sí mímọ́, kí ẹ sì kéde òmìnira fún gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà.+ Yóò di Júbílì fún yín, kálukú yín á pa dà sídìí ohun ìní rẹ̀, kálukú yín á sì pa dà sọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀.+
28 “‘Àmọ́ tí kò bá lágbára láti gbà á pa dà lọ́wọ́ ẹni náà, ohun tó tà máa wà lọ́wọ́ ẹni tó rà á títí di ọdún Júbílì;+ yóò pa dà sọ́wọ́ rẹ̀ nígbà Júbílì, ohun ìní rẹ̀ á sì pa dà di tirẹ̀.+