- 
	                        
            
            Léfítíkù 22:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        20 Ẹ ò gbọ́dọ̀ mú ohunkóhun tó ní àbùkù+ wá, torí kò ní mú kí ẹ rí ìtẹ́wọ́gbà. 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Léfítíkù 22:22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        22 Ẹran tí ẹ fẹ́ fi ṣe ọrẹ ò gbọ́dọ̀ fọ́jú, kò gbọ́dọ̀ kán léegun, kò gbọ́dọ̀ ní ọgbẹ́, èkúrú,* èépá tàbí làpálàpá; ẹ ò gbọ́dọ̀ mú ẹran tó ní èyíkéyìí nínú nǹkan wọ̀nyí wá fún Jèhófà tàbí kí ẹ fi irú rẹ̀ rúbọ lórí pẹpẹ sí Jèhófà. 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Diutarónómì 15:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        21 Àmọ́ tó bá ní àbùkù lára, bóyá ó jẹ́ arọ, afọ́jú tàbí tó ní oríṣi àbùkù míì tó le gan-an, o ò gbọ́dọ̀ fi rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ 
 
-