- 
	                        
            
            Léfítíkù 22:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        20 Ẹ ò gbọ́dọ̀ mú ohunkóhun tó ní àbùkù+ wá, torí kò ní mú kí ẹ rí ìtẹ́wọ́gbà. 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Diutarónómì 17:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        17 “O ò gbọ́dọ̀ fi akọ màlúù tàbí àgùntàn tó ní àbùkù lára tàbí tí ohunkóhun ṣe, rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, torí pé ohun ìríra ló máa jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Málákì 1:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        8 Nígbà tí ẹ bá ń fi ẹran tó fọ́jú rúbọ, ẹ̀ ń sọ pé: “Kò sí ohun tó burú níbẹ̀.” Tí ẹ bá sì ń mú ẹran tó yarọ tàbí èyí tó ń ṣàìsàn wá, ẹ̀ ń sọ pé: “Kò sí ohun tó burú níbẹ̀.”’”+ “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ mú un lọ síwájú gómìnà yín. Ṣé inú rẹ̀ á dùn sí yín, ṣé ẹ sì máa rí ojúure rẹ̀?” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 
 
-