132 Jèhófà, jọ̀wọ́ rántí Dáfídì
Àti gbogbo ìyà tó jẹ;+
2 Bó ṣe búra fún Jèhófà,
Bó ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Alágbára Jékọ́bù pé:+
Mi ò ní dùbúlẹ̀ lórí àga tìmùtìmù mi, àní ibùsùn mi;
4 Mi ò ní jẹ́ kí oorun kun ojú mi,
Mi ò sì ní jẹ́ kí ìpéǹpéjú mi tòògbé
5 Títí màá fi rí àyè kan fún Jèhófà,
Ibùgbé tó dáa fún Alágbára Jékọ́bù.”+