-
Diutarónómì 3:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Àwọn ìyàwó yín àti àwọn ọmọ yín nìkan ni yóò máa gbé inú àwọn ìlú tí mo fún yín, títí kan àwọn ẹran ọ̀sìn yín (mo mọ̀ dáadáa pé ẹ ní ẹran ọ̀sìn tó pọ̀), 20 títí Jèhófà fi máa fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi, bíi tiyín, tí wọ́n á sì gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín máa fún wọn ní òdìkejì Jọ́dánì. Lẹ́yìn náà, kí kálukú yín pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀ tí mo fún yín.’+
-
-
Jóṣúà 1:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Àwọn ìyàwó yín, àwọn ọmọ yín àtàwọn ẹran ọ̀sìn yín á máa gbé ní ilẹ̀ tí Mósè fún yín ní apá ibí yìí* ní Jọ́dánì,+ àmọ́ kí gbogbo ẹ̀yin jagunjagun tó lákíkanjú+ sọdá ṣáájú àwọn arákùnrin yín, kí ẹ tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun.+ Kí ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ 15 títí Jèhófà fi máa fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi, bó ṣe ṣe fún yín, tí àwọn náà á sì gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún wọn. Kí ẹ wá pa dà sí ilẹ̀ tí wọ́n fún yín pé kí ẹ máa gbé, kí ẹ sì gbà á, ilẹ̀ tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà fún yín ní ìlà oòrùn Jọ́dánì.’”+
-
-
Jóṣúà 13:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà tó kù, wá gba ogún wọn tí Mósè fún wọn lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì, bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe fún wọn:+
-