20 Líà wá sọ pé: “Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn, àní ó fún mi ní ẹ̀bùn tó dára. Ní báyìí, ọkọ mi yóò fàyè gbà mí,+ torí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́fà+ fún un.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Sébúlúnì.*+
7 Kí ẹ̀yà Sébúlúnì wá tẹ̀ lé wọn; Élíábù+ ọmọ Hélónì ni ìjòyè àwọn ọmọ Sébúlúnì. 8 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (57,400).+