- 
	                        
            
            Jẹ́nẹ́sísì 46:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        2 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ lójú ìran ní òru, ó ní: “Jékọ́bù, Jékọ́bù!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí!” 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Ẹ́kísódù 24:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        9 Mósè àti Áárónì, Nádábù àti Ábíhù àti àádọ́rin (70) nínú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá gòkè lọ, 10 wọ́n sì rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ Ohun tó dà bíi pèpéle òkúta sàfáyà wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì mọ́ nigínnigín bí ọ̀run.+ 11 Kò pa àwọn èèyàn pàtàkì yìí nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára,+ wọ́n sì rí ìran Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu. 
 
-