16 Kórà+ ọmọ Ísárì,+ ọmọ Kóhátì,+ ọmọ Léfì+ wá gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú Dátánì àti Ábírámù, àwọn ọmọ Élíábù+ pẹ̀lú Ónì ọmọ Péléétì, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì.+ 2 Wọ́n dìtẹ̀ Mósè, àwọn àti igba ó lé àádọ́ta (250) ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ìjòyè àpéjọ náà, àwọn tí a yàn nínú ìjọ, àwọn ọkùnrin tó lókìkí.