- 
	                        
            
            Léfítíkù 11:31, 32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        31 Aláìmọ́+ ni àwọn ẹ̀dá tó ń rákò yìí jẹ́ fún yín. Gbogbo ẹni tó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 32 “‘Tí wọ́n bá kú, ohunkóhun tí wọ́n bá já bọ́ lé yóò di aláìmọ́, ì báà jẹ́ ohun èlò onígi, aṣọ, awọ tàbí aṣọ ọ̀fọ̀.* Kí ẹ ri ohun èlò èyíkéyìí tí ẹ bá lò bọnú omi, yóò sì di aláìmọ́ títí di alẹ́; lẹ́yìn náà, ó máa mọ́. 
 
-