26 “Mo wá ní kí àwọn ìránṣẹ́ láti aginjù Kédémótì+ lọ jíṣẹ́ àlàáfíà+ yìí fún Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì pé, 27 ‘Jẹ́ kí n gba ilẹ̀ rẹ kọjá. Mi ò ní kọjá ojú ọ̀nà, mi ò sì ní yà sí ọ̀tún tàbí òsì.+ 28 Oúnjẹ àti omi tí o bá tà fún mi nìkan ni màá jẹ tí màá sì mu. Ṣáà jẹ́ kí n fi ẹsẹ̀ mi rìn kọjá,