9 “Ṣáà máa kíyè sára, kí o sì máa ṣọ́ra gan-an,* kí o má bàa gbàgbé àwọn ohun tí o fi ojú rẹ rí, kí wọ́n má bàa kúrò lọ́kàn rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Kí o sì tún jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ mọ̀ nípa wọn.+
19 Kí ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín, kí ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ẹ bá jókòó nínú ilé yín, tí ẹ bá ń rìn lójú ọ̀nà, tí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde.+