-
Diutarónómì 6:6-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Rí i pé o fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sọ́kàn, 7 kí o máa fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ+ léraléra,* kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ, nígbà tí o bá ń rìn lójú ọ̀nà, nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.+ 8 So ó mọ́ ọwọ́ rẹ bí ohun ìrántí, kó sì dà bí aṣọ ìwérí níwájú orí rẹ.*+ 9 Kọ ọ́ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn ilé rẹ àti sí àwọn ẹnubodè rẹ.
-