14 Jèhófà wá bínú gidigidi sí Ísírẹ́lì, torí náà, ó fi wọ́n lé àwọn tó ń kóni lẹ́rù lọ́wọ́.+ Ó fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá tó yí wọn ká,+ apá wọn ò sì ká àwọn ọ̀tá wọn mọ́.+
9 Àmọ́ wọ́n gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run wọn, ó sì tà wọ́n+ sọ́wọ́ Sísérà+ olórí àwọn ọmọ ogun Hásórì àti sọ́wọ́ àwọn Filísínì+ àti sọ́wọ́ ọba Móábù,+ wọ́n sì bá wọn jà.