-
Nọ́ńbà 35:25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Kí àpéjọ náà wá gba apààyàn náà sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀, kí wọ́n sì dá a pa dà sí ìlú ààbò rẹ̀ tó sá lọ, kó sì máa gbé níbẹ̀ títí ọjọ́ tí àlùfáà àgbà tí wọ́n fi òróró mímọ́+ yàn fi máa kú.
-
-
Diutarónómì 19:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 “Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí apààyàn tó bá sá lọ síbẹ̀ kó má bàa kú nìyí: Tó bá ṣèèṣì pa ẹnì kejì rẹ̀, tí kò sì kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀;+ 5 bóyá òun àti ẹnì kejì rẹ̀ jọ lọ ṣa igi nínú igbó, tó wá gbé àáké sókè láti gé igi, àmọ́ tí irin àáké náà fò yọ, tó ba ẹnì kejì rẹ̀, tó sì kú, kí apààyàn náà sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú yìí, kó má bàa kú.+
-