19 Torí lẹ́yìn tí Mósè sọ gbogbo àṣẹ inú Òfin náà fún gbogbo èèyàn, ó mú ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ ọmọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́, pẹ̀lú omi, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti ewéko hísópù, ó sì fi wọ́n ìwé náà àti gbogbo àwọn èèyàn náà, 20 ó sọ pé: “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run pa láṣẹ pé kí ẹ pa mọ́.”+