-
Diutarónómì 4:40Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
40 Kí o máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà àti àwọn àṣẹ rẹ̀, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ, kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.”+
-
-
Diutarónómì 12:28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 “Rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún ọ yìí, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ nígbà gbogbo, torí pé ò ń ṣe ohun tó dáa tó sì tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
-
-
Róòmù 10:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Nítorí Mósè kọ̀wé nípa òdodo tó wá látinú Òfin pé: “Yóò mú kí ẹni tó bá ń pa àwọn ohun tó sọ mọ́ wà láàyè.”+
-