3 Jékọ́bù wá sọ fún Jósẹ́fù pé:
“Ọlọ́run Olódùmarè fara hàn mí ní Lúsì nílẹ̀ Kénáánì, ó sì súre fún mi.+ 4 Ó sọ fún mi pé, ‘Màá mú kí o bímọ, màá sì mú kí o di púpọ̀, màá sọ ọ́ di àwùjọ àwọn èèyàn,+ màá sì fún àtọmọdọ́mọ rẹ ní ilẹ̀ yìí kó lè di ohun ìní wọn títí láé.’+