12 “Ní báyìí, ìwọ Ísírẹ́lì, kí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ kí o ṣe?+ Kò ju pé: kí o máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ kí o máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí o máa fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+
13 “Tí ẹ bá ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́ délẹ̀délẹ̀, èyí tí mò ń pa fún yín lónìí, tí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín, tí ẹ fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín sìn ín,+
6 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa wẹ ọkàn rẹ mọ́* àti ọkàn ọmọ+ rẹ, kí o lè fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì máa wà láàyè.+