-
Jóṣúà 23:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “Àmọ́ tí ẹ bá yí pa dà pẹ́nrẹ́n, tí ẹ sì rọ̀ mọ́ ìyókù àwọn orílẹ̀-èdè yìí, tí wọ́n ṣẹ́ kù+ pẹ̀lú yín, tí ẹ bá wọn dána,*+ tí ẹ sì ń bára yín ṣọ̀rẹ́, 13 kí ẹ mọ̀ dájú pé Jèhófà Ọlọ́run yín kò ní bá yín lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí kúrò* mọ́.+ Wọ́n máa di pańpẹ́ àti ìdẹkùn fún yín, wọ́n máa di pàṣán ní ẹ̀gbẹ́ yín+ àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ fi máa pa run lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà Ọlọ́run yín fún yín.
-
-
1 Àwọn Ọba 11:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Àmọ́ Ọba Sólómọ́nì nífẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀ obìnrin ilẹ̀ àjèjì,+ yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Fáráò,+ àwọn tó tún nífẹ̀ẹ́ ni: àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ Móábù,+ ọmọ Ámónì,+ ọmọ Édómù, ọmọ Sídónì+ àti ọmọ Hétì.+ 2 Wọ́n wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ lọ sí àárín wọn,* wọn ò sì gbọ́dọ̀ wá sí àárín yín, torí ó dájú pé wọ́n á mú kí ọkàn yín fà sí títẹ̀lé àwọn ọlọ́run wọn.”+ Àmọ́ ọkàn Sólómọ́nì kò kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn.
-